HYMN 824

(FE 861)
"Nitorina ki enyin ki o pe" - Matt.5:48



1.  JEK' A l’ayo ninu Jesu 

     Oba Alayo ni Jesu 

     Enikeni ti ba r’ayo Re gba 

     Banuje re y'o si fo lo.


2.  Wo sa gba Oruko Re gbo

     Ki o si tun gbekele

     Ko si m’adura to wa nin'eje Re 

     Banuje re y'o si fo lo.


3.  Kerubu ati Serafu

     Wo ha tun nbanuje bi?

     Kristi nso fun o, ke Halleluyah 

     Banuje re y’o si fo 1o.


4.  Esu lo ha nderu ba o?

     Oso tabi aje ni?

     Pe Oruko Jesu nigbagbogbo 

     Banuje re y‘o si fo lo.


5.  K'a ni ife gbogbo aiye 

     Ki se s’omo egbe nikan

     Gbana adura re y’o si goke

     Banuje re y‘o si fo lo.


6.  Gbogbo enyin eda aiye 

     Juba oruko Jesu

     Oruko yi to fun banuje re 

     Banuje re y’o si fo lo.


7.  Ranti pe On l’Eni Yanu 

     Oba Oludamoran 

     Alagbara, Baba aiyeraiye 

     Alade Alafia.


8.  A f’ogo fun Baba l’oke

     A f’ogo fun Omo Re

     Ogo ni fun Emi t’o ndari wa 

     Metalokan wa gb’ope wa.  Amin

English »

Update Hymn