HYMN 821

H.C No 57 Edn. 6.8s (FE 857) 
"Nitorlpe apata won ko dabi apala wa
- Deut. 32:31
Tune: lgbagbo mi duro lori



1.  E jek‘ a yin Olugbala 

     T'o da Emi wa si di oni

     Nitori a ko mo ojo

     T'o mbo wa se 'dajo aiye 

    Ojo kan mbo gba aiye ba pin 

    Kerubu yio ko 'rin Alleuyah.


2.  Ojo ‘dajo ojo eru

     Gba Jesu yio ya Agutan Re 

     Kuro ninu agbo esu

     Gbana ipe nla yio si dun 

     Gbogbo aiye yio wa si idajo 

     Serafu yio ko ‘rin Alleluyah.


3.  Awon elese yio fe sa

     Kuro niwaju Olugbala 

     Sugbon iye ko ni si mo 

     Nwon yio ke gba mi Oluwa 

     Sugbon ojo anu koja 

     Kerubu yio ma ko Alleluyah.


4.  Ara mi jek’ a gba adura 

     S'Olorun Metalokan

     Tori on lo da aiye

     Ati gbogbo eda ‘nu re

     Yio si ko awon Tire jo 

     Lati ma korin niwaju ite.  Amin

English »

Update Hymn