HYMN 812

8.8.6. D
Tune: “Lehin aye buburu yi”



1.  EMI ogbon, to oju wa 

     Kuro ninu asan aye 

     S’oto on ‘fe orun 

     Emi oye ti o daju

     Fi mole orun fun wa 

     Lati wa nkan toke.


2.  Emi ‘moran s’Amona wa 

     F’ijakadi aye ko wa

     K’a gba ade t’orun

     Emi ‘gboya, k’agbara Re 

     Ran wa lowo nigba ‘danwo 

     Pa wa mo lailese.


3.  Emi imo, to ese wa

     Li ona Re ti ko l’ewu 

     T’awon angel ‘ti rin 

     Nib i t’Iwo Oluto wa 

     Iwo Emi ifokansin 

     Mu wa sunm’Olorun.


4.  Sunmo wa lojo aye wa 

     Emi iberu Olorun

     N’ikoko aya wa

     F‘owo t’o ye kun okan wa 

     Lati sin ife mimo Re

     T'o l'ododo julo.


5.  Ma to wa lo l'alafia

     Sinu iye ainipekun

     K'a jere giga na

     K’a ja ogun aye wa yi

     Nipa agbara Re mimo

     K'a si ba Krist'joba.  Amin

English »

Update Hymn