HYMN 811

H.C 421 8s 7s (FE 846)
"Awon ologbon yio si ma tan bi
imole ofurufu" - Dan. 12:3



1.  TAL’awon wonyi bi ‘irawo 

     Niwaju ite Mimo
 
     Ti nwon si de ade wura 

     Egbe ogo wo l’eyi 

     Gbo! nwon nko Halleluya

     Orin iyin Oba won! 


2.  Tali awon ti nko mana

     T’a wo l’aso ododo?

     Awon ti aso funfun won

     Y’o ma funfun titi lai

     Beni ki y’o gbo lailai

     Nibo l’egbe yi ti wa? 


3.  Awon wonyi l’o ti jagun 

    F’ola Olugbala won 

    Nwon jijakadi titi iku 

    Nwon ki b'elese k'egbe

    Wonyin ni ko sa f’ogun 

    Nwon segun nipa Kristi.


4.  Wonyi l'okan won ti gbogbe

     Ninu ‘danwo kikoro

     Wonyi ni o ti f’adura

    Mu Olorun gbo ti won 

    Nisisyi won segun

    Olorun re won lekun.


5.  Awon wonyi l’o ti sora

    Ti won fi fe won fun Krist’

    Nwon si y’ara won si mimo 

    Lati sin nigbagbogbo

    Nisisiyi li orun

    Nwon wa l’ayo l’odo Re.  Amin

English »

Update Hymn