HYMN 81

SS. 207 8s (FE 98)
“Eyo ni Oluwa” - Ps. 68:3



1.  E YO nin‘Oluwa, e yo

     enyin olokan diduro

     At‘enyin t’ase l’ayanfe

    Mu ‘banuje kuro l’okan nyin.

Egbe:  E yo, e yo, e yo nin’ Oluwa, 

            e yo. 2ce


2.  E yo n’tori On l’Oluwa,

     L’ aiye ati l’orun pelu

     O njoba nipa ase Re,

     O l'agbara lati gbala.

Egbe:  E yo, e yo...


3.  Nigbati ogun ba gbona

     T‘ota ba fere segun nyin

     Ogun Jesu ti a ko ri,

     Po ju gbogbo otan nyin lo.

Egbe:  E yo, e yo...


4.  B’osan d‘orun mo nyin loju,

     T’okunkun re nderu ba nyin

     E ma je k’okan nyin baje

     Gbekele tit’ ewu yio tan.

Egbe:  E yo, e yo...


5.  E yo nin’Oluwa, e yo

     E f’orin didun yin logo

     Fi duru, fere, at’ohun

     Korin Halleluyah kikan.

Egbe:  E yo, e yo...  Amin

English »

Update Hymn