HYMN 806

APA KINI (FE 841)
“Tali o dabi Re Olorun Elenu ni iyin”
- Eks. 15:11



1.  OLORUN agbaiye,

     Owo ni f’Oruko re 

     Iwo l’agbekele, 

     lai ma je k’oju ti wa. 

Egbe: Bi kose pe O ko ile na, 

          Osise nse lasan, 

          Wo Alfa ati Omega 

          Ran iranwo re si wa.


2.  Oba aiku, Airi, Mimo logo julo 

     Eni aiyeraiye, t’o gunwa 

     n‘nu ‘mole nla.

Egbe: Bi kose pe O...


3.  L’aiye ati l’orun, tani a ba fi we O! 

     Eleda, Alase, Baba

     Olodumare.

Egbe: Bi kose pe O...


4.  Iwo l’o da aiye, ati ohun inu re 

     O da awon orun, ati gbogbo

     ogun won.

Egbe: Bi kose pe O...


5.  Baba wa olore, at’oniyonu julo 

     Eleru ni iyin, Olorun alagbara.

Egbe: Bi kose pe O...


6.  Metalokan lailai, Baba, 

     Omo on Emi 

     Ipilese, Opin, Mimo Awamaridi.

Egbe: Bi kose pe O...


7.  Ogo f’oruko re, t’o ju 

     gbogbo iyin lo

     Iwo ni yin ye fun, tit’ aye 

     ainipekun.

Egbe: Bi kose pe O ko ile na, 

          Osise nse lasan, 

          Wo Alfa ati Omega 

          Ran iranwo re si wa.  Amin

English »

Update Hymn