HYMN 805

C.M. (FE 840)
"Oluwa li olupamo Re” - Ps.121:5 
Tune: Emi Ba l’egberun Ahon



1.  OLUPAMO gbogbo eda, 

     Oba Asekan-maku 

     Awa fi malu ete wa 

    Rubo ope si O.


2.  T’Omode at’agba dupe 

     F’abo Re loni wa 

     Fun ike ati ise Re 

     Lori wa lat‘esi.


3.  E bu s‘ayo Omo Ogun 

     Ati gbogbo egbe 

     Ajodun t’oni t'o ba wa 

     Lorile alaye.


4.  Eleru, Niyi, a be O

     Se wa l’enia Re

     K’a mase pada lodo Re 

     K’a le sin O dopin.


5.  Awa si mbebe siwaju 

     Nin'odun t'a wa yi

     Fi ohun rere kari wa 

     S’aiye wa ni rere.


6.  Oba amona gbogb’eda 

     S'amona wa dopin

     Ma jek’ esu ba wa d'egbon 

     Ma jek’ a padanu.


7.  B’a ti njosin, t‘a si nyin O 

     L’aginju aiye yi 

     Se wa ye k’a tun le yin O 

     Loke orun pelu.  Amin

English »

Update Hymn