HYMN 804

(FE 839)
Olorun reti pase agbara re" - Ps. 68:28
Tune: Baba Mimo Jo gbo gbe Omo Re



1.  DIDE tan imole, Imole Owuro 

     Jeki ogo Oluwa yo lara re

     Okunkun ese ti bo aiye mole 

     Sugbon ewa ayanfe ti jade.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

           E ke Hosannah s’Oba Ogo 

           Apata aiyeraiye jowo

          mu ‘Ieri' re se.


2.  Awon keferi y'o wa si‘imole Re 

     Awon Oba y’o teriba fun O

    Gbe oju re soke ki o wo yika 

    Siro ‘rawo, siro ‘bukun loke.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

           E ke Hosannah s’Oba Ogo 

           Apata aiyeraiye jowo

          mu ‘Ieri' re se.


3.  Omo alejo ni y'o mo odi re 

     Awon Oba y’o se ‘ranse fun o 

     Awon aninilara re y’o d'ofo 

    Y’o pa won elegan lenu mo.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

           E ke Hosannah s’Oba Ogo 

           Apata aiyeraiye jowo

          se isadi wa.


4.  Orun banuje ki y'o ran si wa mo 

     Osupa ekun wa mbo wa dopin 

     Emi Jehovah y'o mu oro mi se, 

     Lati mu Oba wa gunwa loke. 

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

           E ke Hosannah s’Oba Ogo 

           Apata aiyeraiye jowo se abo

          wa loke Re.


5.  Mo se o ni wura asayan loni 

     Emi agbara mi mbe lara re 

     Abo aso eri kuro lara re 

     Aso eye la fi dipo fun O.

Egeb: Wa ore mi, e wa k’a jo yo

           E ke Hosannah s’Oba Ogo 

           Apata aiyeraiye nikan

          l'ope ye fun loni.  Amin

English »

Update Hymn