HYMN 802

Tune: 7s



1.  E fi ogo fun Baba

     Nipa Eni ti a wa

     O ngbo adura ewe 

     O nf’eti si orin won.


2.  E fi ogo fun Omo 

     Kristi, ‘Wo ni Oba wa 

     E wa, e korin s’oke

     S’Od’agutan elese.


3.  Ogo fun Emi Mimo

     Bi ojo Pentikosti

     Ru aya awon ewe 

     F’orin mimo s’eti won.


4.  Ogo ni l’oke orun 

     Fun Eni Metalokan 

     Nitori ihin rere

     Ati ife, Olorun.  Amin


English »

Update Hymn