HYMN 798

t.GB 466 (FE 833)
“A wo won ni aso funfun, imo ope
si mbe li owo won” - Ifi.7:9
Tune: “Olorun kan l'o to k’a sin”



1.  ENYIN ero nibo l’e nlo 

     T‘enyin ti ‘mope,

     lowo nyin?

     Awa nlo pade Oba wa 

    Gegebi ‘leri re si wa.

Egbe: A nlo s’afin, s’afin Oba rere, 

          A nlo s’ile ‘leri, nibiti

          ese ko le de

          Nibiti simi wa lailai.


2.  Enyin, ero, e so fun wa 

     T’ayo pipe ti mbe nibe 

     T’aso ala at’ade Ogo

     Ti Jesu y’o fun wa loke.

Egbe: A nlo s’afin...


3.  A ko ni ‘bugbe kan nihin 

    O buru bi ‘hin je le wa 

    Ayo l’ogo ekun lale 

    Sugbon eyi ko si loke.

Egbe: A nlo s’afin...


4.  Egbe orun, e silekun 

     F’egbe aiye lati wole 

     Awa n’ise at’iponju

     Nwon de lati b’Oluwa gbe.

Egbe: A nlo s’afin...


5.  Ogunlogo nibi gbogbo 

     Ti nwon ti segun aiye yi 

     Olorun so won di omo 

     Wa ore mi, ki ile to su.

Egbe: A nlo s’afin...


6.  Oja aiye, oja asan 

     B’Oluwa n’oja, k’o jere 

     Ore aiye, ore asan 

     B’Oluwa s’ore, ki idani.

Egbe: A nlo s’afin...


7.  Wo! ko tun s’adun laiye mo 

      Ibjae po rere lo

      B’Olowa re, pinnu loni

      Ki ‘gbehin re ba le layo.

Egbe: A nlo s’afin...


8.  Agbagba merinlegun 

     Enyin l’awa fe ba k’egbe 

     Tori ko s’adun laiye mo 

     E ka wa ye f’adun loke.

Egbe: A nlo s’afin, s’afin Oba rere, 

          A nlo s’ile ‘leri, nibiti

          ese ko le de

          Nibiti simi wa lailai.  Amin

English »

Update Hymn