HYMN 795

O.t.H. C. 289 C.M. (FE 829)
"E mase fe aiye" - 1John. 2:15



1.  AWA fe ohun aiye yi 

     Nwon dara l‘oju wa 

     A fe k‘a duro pe titi 

     Laifi won sile lo.


2.  Nitori kini a nse be? 

     Aiye kan wa loke 

     Nibe l'ese on buburu 

     Ati ewu ko si.


3.  Aiye t’o wa loke orun

     Awa iba je mo

     Ayo, ife inu rere 

    Gbogbo re wa n’be.


4.  Iku, o wa ni aiye yi 

     Ko si loke orun 

     Eniyan Olorun wa mbe 

     Ni aye ni aiku.


5.  K’a ba ona ti Jesu lo

     Eyi t'O la fun wa

     Sibi rere, sibi simi

     S’ile Olorun wa.  Amin

English »

Update Hymn