HYMN 794

C.M.S 479. H.C 511 8.6
8.6.8 (FE 828)
"Nwon ti fo aso igunwa won, nwon 
si so nwon di funfun ninu eje 
odo-agutan” - Ifi.7:14



1.  YIKA or’ite Olorun 

     Egberun ewe wa,

     Ewe t'a dari ese ji 

     Awon egbe mimo 

    Nkorin Ogo, ogo, ogo.


2.  Wo! olukuluku won wo, 

     Aso ala mimo

     Ninu imole ailopin 

     At'ayo ti ki sa,

    Nkorin Ogo, ogo, ogo.


3.  Kil‘o mu won de aiye na, 

     Orun t’o se mimo

     Nib’ alafia at’ayo

     Bi nwon ti se de ‘be? 

     Nkorin Ogo, ogo, ogo.


4.  Nitori Jesu ta ‘je Re, 

     Lati k‘ese won Io;

     A ri won uinu eje na, 

    Nwon di mimo laulau, 

    Nkorin Ogo, ogo, ogo.


5.  L‘aiye, nwon wa Olugbala 

     Nwon fe oruko Re, 

     Nisisiyi nwon r’oju Re, 

     Nwon wa niwaju Re, 

     Nkorin Ogo, ogo, ogo.


6.  Orisun na ha nsan loni?

     Jesu, mu wa de be

     K‘a le ri awon mimo na 

     K'a si ba won yin O,

     Nkorin Ogo, ogo, ogo.  Amin

English »

Update Hymn