HYMN 790

C.M. (FE 824)
“E mu iyin Re Ii ogo" - Ps.66:2



1.  GBOGBO talaka ti mo mo 

     Nwonti po n’iye to 

     Kini mba se f’Olorun mi 

     Fun gbogbo ebun Re?


2.  Mo san j’awon elomi ni 

     T’Olorun se nke mi? 

     Awon ti nkiri, ti nsagbe 

     Lati ile de ‘le?


3.  Alakisa omo melo 

     Ni mbe l'otutu yi? 

     Gbati a fi aso wo mi 

     Lat' ori d‘ese mi.


4.  Gba t’awon mi se alairi 

     Ibi gb‘ori won le 

     Emi ni ile lati gbe

     Ati ‘bukun rere.


5.  Gbat awon mi, ti nwon npuro 

     Ti njale, ti mbura

     Ni mo ti ko iberu Re

     Lati igba ewe mi.


6.  Sa wo, bi oju rere Re

     S'emi nikan ti po

     Nje o ye ki nfe O pupo

     Ki nma sin O rere?  Amin

English »

Update Hymn