HYMN 789

C.M. (FE 823)
"Olorun yio busi fun wa" - Ps. 67:7



1.  IBUKUN ni fun agbara

     Ododo on Ogbon 

     At’Ore-ofe t‘o papo 

     S'Ise Igbala wa.


2.  Baba wa j’eso-gi aije 

     Ogo Re si wo mi 

     Awa omo re si d’eru 

     Esu ati Iku.


3.  Ope fun Baba t’o f'Omo 

     Re kansoso fun wa 

     Enit’O ku, k’awa le ye 

     Ka le d’om'Olorun.


4.  Ofin Baba gbogbo t’a ru 

     L’Omo ti a pa mo

     O ku lori agbelebu 

     Nitori ese wa.


5.  Wo! O Ji dide n‘iboji 

     O si goke r’orun 

     Nibe li O nf’ ltoye Re 

     Gba gbogb’ arufin la.


6.  O gunwa lor’ite ogo 

     Pelu agbara nla

     O f’ewon ide ese ja 

     T'Esu ti fi de wa. 


7.  O si tun mbo wa se ‘dajo

     Pelu ola-nla Re

     Y’o pe awon oku mimo 

     Jade pelu ayo.


8.  Mba le duro l'ayo pelu 

     N’waju O n d‘dajo yi!

     Ki nsi korin irapada

     Pel‘ awon t'a gbala.  Amin

English »

Update Hymn