HYMN 788

C.M (FE 822)



1.  OGO OBA wa ti po to 

     Ti mbe l’oke orun, 

     Omo-kekere wo l’o le, 

     Korin ola ‘nla Re.


2.  Ta l’o le rohin ipa Re 

     At’ore-ofe Re

     Ko s’enikan l’aiye l’orun 

     To mo titobi won.


3.  Angeli t’o yi Oluwa ka

     Ko je so ‘tumo re

     Sugbon nwon npa ase re mo 

     Nwon si nkorin ‘yin Re.


4.  Nje mo fe ma ba won korin 

     Ki nm’ore temi wa 

     Oga-Ogo ki y’o kegan 

     Ohun orin ewe.


5.  Mura, okan at'o ahno mi, 

     Lati korin iyin 

     S’Olodumare Eleda

     Ayo aw’Angeli.  Amin

English »

Update Hymn