HYMN 787

(FE 821)
“Yin I gegebi titobi re“ - Ps.150:2
Tune: Oluwa fise ra mi Alleluya



1.  E BA wa korin iyin Halleluya 

     E ba wa yin Oba Ogo,

     To da wa si di oni

     Halleluyah!

     E ba yin Oba Ogo.

Egbe: Bus’ayo, arakunrin 

           E gbe orin iyin 'ga, 

           Bu s’ayo, arabinrin, 

           Halleluya!

           E wa gbe Ebenezer ro.


2.  E ba wa korin iyin

     Halleluya

     Fun isegun t’O fi fun wa,

     Ti ko jek’ota yo wa Halleluya 

     E ba wa yin Oba Ogo.

Egbe: Bu s’ayo... 


3.  E ba wa korin iyin,

     Halleluyah

     Fun ‘se ‘yanu to se larin wa, 

     To fo itegun Esu, Halleluya! 

     T’o mu wa la ‘danwo koja.

Egbe: Bu s’ayo... 


4.  E ba wa korin iyin, 

     Halleluya!

     Fun idagbasoke emi wa, 

     To pe wa sinu agbo, 

     Halleluya!

     Ti ko je ka d’eni gbajare.

Egbe: Bu s’ayo... 


5.  Iyin f’Olorun Baba 

     Halleluya!

     Iyin fun Olorun Omo, 

     Iyin fun Emi Mimo Halleluya!

     Metalokan la fi ‘yin fun.

Egbe: Bus’ayo, arakunrin 

           E gbe orin iyin 'ga, 

           Bu s’ayo, arabinrin, 

           Halleluya!

           E wa gbe Ebenezer ro.  Amin

English »

Update Hymn