HYMN 786

(FE 820)
"Awon ti o gba ti Olorun gbo nwon
o ri iye ainipekun”
Tune: Jesu Mo wa Sodo Re



1.  A DUPE lowo Olorun 

     T'O fi Jesu kristi fun wa, 

     Lati ra raiye pada

     Lowo ese ati esu.

Egbe: E yin logo, e f'ope fun 

          Olorun Metalokan 

          Fun anu at'ore Re

          Lori gbogbo Egbe Serafu.


2.  Agbara Olorun ndagba 

     Ogo Jesu nhan si wa 

     Agbara Emi Mimo wa, 

     Larin Egbe Serafu.

Egbe: E yin logo...


3.  Gbogbo enia at’orile-ede 

     Dorikodo s‘adura

     E yipada l’emi oto

     Ki Baba orun gba wa. 

Egbe: E yin logo...


4.  Ese po, aiye yi daru

     Esu njale, o si nyo 

     K’onigbagbo pe adura po 

     K’a Ie segun ese at‘esu.

Egbe: E yin logo...


5.  Olufokansin onigbagbo 

     Jesu mo ise ikoko re

     Mase lo, l’ohun Oluwa nwi 

     Oluko re nsunmole.

Egbe: E yin logo...


6.  Kerubu, Serafu, mura 

     Alufa, Bishop, mura 

     Enyin to mo Jesu, e mura 

     Lojo kehin ojo dajo.

Egbe: E yin logo...


7.  Ajodun miran l’awa nse 

     T’Olorun ran Moses 

     Lati s’egbe yi loruko 

     Ogun orun Serafu.

Egbe: E yin logo...


8.  Egbe Mose, e mura dide 

     Larin egbe Kerubu, Serafu 

     Olorun Baba lo fun wa 

     Gbe asia re soke.

Egbe: E yin logo...


9.  Keferi, Imale, ewa 

     Onigbagbo, e ma kalo 

     Ka jo yin Olorun logo 

     Ka le gba ade iye.

Egbe: E yin logo...


10.  Olorun Baba sanu wa 

       Dariji wa, pa wa mo 

       Ran wa lowo, gbadura wa 

       Titi aiye ainipekun.

Egbe: E yin logo, e f'ope fun 

          Olorun Metalokan 

          Fun anu at'ore Re

          Lori gbogbo Egbe Serafu.  Amin

English »

Update Hymn