HYMN 785

C.M.S 139 H.C 136 C.M (FE 819)
"Emi o si fi ota sarin iwo ati obinrin na 
ati iru omo re ati omo re, on o fo o li ori 
iwo o si pa a ni gigisi." - Gen. 3:15



1.  lYlN f‘Eni Mimo julo 

     Loke ati n'ile 

     Oro Re gbogbo je ‘yanu 

     Gbogb‘ ona Re daju.


2.  Ogbon Olorun ti po to! 

     ‘Gbat’enia subu

     Adam keji wa s’oju ja 

     Ati lati gbala.


3.  Ogbon ife! p‘eran ara 

     T‘o gbe Adam subu 

    Tun b‘ota ja ija otun 

    K‘o ja k‘o si segun.


4.  Ati p’ebun t'o f’or-ofe 

     So ara di otun

     Olorun papa Tikare 

     J'Olorun ninu wa.


5.  Ife ‘yanu! ti Eniti 

     O pa ota enia

     Ninu awo awa enia 

     Je irora f’enia.


6.  Nikoko ninu ogba ni 

     Ati l’ori igi

     T’o si ko wa lati jiya 

     To ko wa lati ku.


7.  Iyin f’Eni Mimo julo

     L'oke ati n’ife 

     Oro Re gbogbo je ‘yanu 

     Gbogb’ ona Re daju.  Amin

English »

Update Hymn