HYMN 783

(FE 817)
"Oba awin oba ati Oluwa awon 
Oluwa" - Ifi. 19:16



1.  E WOLE f'Oba wa 

Omo Mimo Baba 

Eleda, Alabo

Olugbala gbogbo araiye. 

Egbe: Gbogbo aiye, e fori bale

f 'Olodumare

Enit'o ra wa pada

Alleluya gb’orin segun na ga 

Metalokan wa l'Oba ogo.


2.  Mi si wa, Oluwa

Ka pin ‘nu ogo Re 

Orisun iye wa 

Ato-bajaiye Oba ogo.

Egbe: Gbogbo aiye...


3.  Aiye pel’ekun re

Tire ni Oluwa

Awon to gba O gbo

Ni yio jogun Re titi aiye.

Egbe: Gbogbo aiye...


4.   lkore aiye gbo

      E mura, araiye 

      Olukore fere de 

      Alikama nikan ni Tire.

Egbe: Gbogbo aiye...


5.  Lojo ifarahan

     Jewo mi, Oluwa

     Jek‘ore-ofe Re

     Mu wa ye lati ba O gunwa.

Egbe: Gbogbo aiye, e fori bale

           f 'Olodumare

           Enit'o ra wa pada

           Alleluya gb’orin segun na ga 

           Metalokan wa l'Oba ogo.  Amin

English »

Update Hymn