HYMN 782

C.M.S 545 t.H.C 60 7s (FE 816)
"Emi ki gbe pe O, Oluwa” - Ps.30:8
Tune: A gboju s’oke si O



1.  WA, Jesu fi ara han,

     Wa, jek'okan wa mo O 

     Wa, mu gbogb’okan gbona 

     Wa, bukun wa k‘a to lo.


2.  Wa, f’aiya wa n’isimi 

     Wa, k’a d’alabukunfun 

     Wa, soro alafia

     Wa, busi igbagbo wa.


3.  Wa, le ‘siyemeji lo 

     Wa, ko wa b’a ti bebe 

     Wa, fun okan wa n'ife 

     Wa, fa okan wa soke.


4.  Wa, so f‘okan wa k‘o yo 

     Wa, wipe “Wo ni mo yan 

     Wa, p'awon agbo Re mo 

     Wa, sure f’agutan Re.  Amin

English »

Update Hymn