HYMN 781

(FE 815)
“Okan mi yio sure fun O" - Gen. 27:4



1.  SURE fun wa loni, Baba wa orun 

     A gboju wa soke si O,

    We to sure f’Abraham

     baba wa,

     Jowo sure fun wa.

Egbe: Alpha ati Omega

          A si okan wa paya fun O, 

          Ma je ka lo Iofo.


2.  Metalokan Mimo Alagbara 

     lfe to jinle julo

     Awamaridi Olodumare 

     Jo f'ire kari wa.

Egbe: Alpha ati Omega...


3.  Awa nke pe O loni, Baba wa, 

     Ma je k’omo Re rahun

     Ko sohun ti jamo lehin ekun 

     Jowo dabobo wa.

Egbe: Alpha ati Omega...


4.  Wo lo m'omi lat’inu apata 

     F’awon enia Re saju

     O rojo manna pelu lat’orun 

     Jowo pese fun wa.

Egbe: Alpha ati Omega

          A si okan wa paya fun O, 

          Ma je ka lo Iofo.  Amin

English »

Update Hymn