HYMN 780

(FE 814)
"Ma beru nitori emi wa pelu re"
- Isa. 43:5



1.  OLORUN wa mbe larin wa, 

     Y‘o si bukun gbogbo wa, 

    Wo oju orun b‘o li su

    Yio rojo ibukun.

Egbe: K'o de, Oluwa, a be O

          Je k'ojo ibukun de,

          Awa nduro, awa nduro, 

         M'okan gbogbo wa soji.


2.  Olorun wa mbe larin wa, 

     Ninu ile mimo yi; 

     Sugbon a nfe ‘tura okan 

     Ati opo ore-ofe.

Egbe: K'o de, Oluwa...


3.  Olorun wa mbe larin wa; 

     K‘a f'okan 'gbagbo bere 

     Ohun t‘a fe lowo Re, ki 

     ‘Fe Re m’okan wa gbona.

Egbe: K'o de, Oluwa...


4.  Olugbala gb‘adura wa,

     B'a ti f‘igbagbo kunle

     Jo si ferese anu Re

     K’o da ‘bukun sori wa.

Egbe: K'o de, Oluwa, a be O

          Je k'ojo ibukun de,

          Awa nduro, awa nduro, 

         M'okan gbogbo wa soji.  Amin

English »

Update Hymn