HYMN 78

8.7 (FE 95)
"Olorun si pe iyangbe ile ni ile" - Gen. 1:10
Tune: Ope lo ye f'Olugbala"



1.  T'OLORUN Oluwa nile

     Ati gbogbo ekun re,

     Aiye at'awon enia

     Ti O tedo sinu re.

Egbe:  Awamaridi ni 'se Re,

           OLuwa omo-ogun

           Ogo Ogo ola at'agbara,

           Ni fun O, Metalokan.


2.  Tani yio goke Oluwa

     Ati ibi Mimo Re

     Enit’o ni owo mimo

     TI aiyaa re si funfun.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...


3.  Awon ti ko gbokan soke

     S'ohun asan aiye yi,

     Ti ko si je bura etan

     Yio ri ‘bukun Oluwa gba.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...


4.  Eyi I’awon ti nsaferi

     Oju Olorun Jakobu,

     Awon to duro d'Oluwa

     Ni yio ri ‘bukun gba.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...


5.  Gbori soke enu ona,

      Ka si tun gbe nyin soke

      Enyin l‘ekun aiyeraiye,

      K'Oba ogo le wole.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...


6.  Tani Oba Ologo yi!

     Oluwa Omo Ogun

     Eni to I'agbara l‘ogun

     On ni Oba Ogo yi.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...


7.  Gbori soke enu ona,

     K'Oba ogo le wole

     Tani Oba Ogo yi?

     Oluwa Omo Ogun.

Egbe:  Awamaridi ni 'se...  Amin

English »

Update Hymn