HYMN 779

C.M.S 548 10s (FE 813)
"Oluwa k’o fi alafia busi fun
awon enia Re" - Ps.29:11



1.  OLUGBALA, a tun fe f’ohun kan 

     Yin Oruko Re ka to lo si le 

     N’ipari isin, a ntor’anu Re

     Ao si kunle fun ibukun Re.


2.  F’alafia fun wa ba ti nrele 

     Je ka pari ojo yi pelu Re 

     Pa aiya wa mo, si so ete wa 

     T’a fi npe oruko re nihin yi.


3.  F’alafia fun wa loru oni 

     So okunkun re di imole fun wa 

     Ninu ewu yo awa omo Re 

     Okun on ‘mole j'okanna fun O.


4.  F’alafia fun wa loj’aiye wa

     Re wa lekun, ko si gbe wa nija 

     Gbati’ O ba si f’opin si idamu wa 

     Pe wa, Baba, s’orun Alafia.  Amin

English »

Update Hymn