HYMN 777

(FE 811) 8s7s
"O si wi fun u pe, Emi ni Jehovah"
- Ex.6:2
Tune: Ma toju mi Jihofa Nla



1.  JESU Olori Egbe wa, 

     Bukun wa k‘awa to lo 

     Baba Olorisun gbogbo 

     Je ka ri O larin wa.

Egbe: Jah Jehovah! Jah Jehovah!

           Kabiyesi Oba wa - 6x


2.  Jowo Jesu awa mbe O,

     K‘a ma ri agbako aiye

     K ari 'se se, k‘oja k’o ta, 

     K‘omo Re ma rahun mo.

Egbe: Jah Jehovah!...


3.  Sure fun wa l‘ojo aiye wa, 

     K‘ebi ale ma pa wa, 

     K’enikeni mase rahun 

     M’ese Egbe wa duro.

Egbe: Jah Jehovah!...


4.  Ma je ki fitila re ku, 

     Larin Egbe Serafu 

     Gege bi Serafu t’orun 

     Ki gbogbo wa jo yin O.

Egbe: Jah Jehovah!...


5.  Rant’ egbe t’o wa l’okere 

     Fun won l'okun ilera

     Aje, oso ko ma ri won, 

    Iwo lo ns’Alabo won.

Egbe: Jah Jehovah!...


6.  Jehovah Jireh Oba wa, 

     Jehovah Nissi Baba

     Johovah Shalom,

     S’amona wa lojo ‘ku.

Egbe: Jah Jehovah! Jah Jehovah!

           Kabiyesi Oba wa - 6x  Amin

English »

Update Hymn