HYMN 774

8.6.8.6.8.8.8.6



1.  E wa k’a jo jumo korin 

     Ife ni Olorun

     Orun, aye mu yin won wa 

     Ife ni Olorun

     Ki gbogbo okan ji kuro 

     Ninu ese ki won f’ayo 

     Korin didun n’tori Jesu 

     lfe ni Olorun.


2.  E so ni gbogbo agbaye 

     Ife ni Olorun

     N’nu Krist’ l’ekun ‘rapada wa 

     Ife ni Olorun

     Eje Re le w’ese wa nu

     Emi Re s’oru wa d’osan

     O nto ‘kan wa lati so pe 

     Ife ni Olorun.


3.  Ayo ni ipin wa nihin 

     Ife ni Olorun

     Okan wa nyo si ‘leri Re 

     Ife ni Olorun

     Orun at’ abo wa losan

     O si mba wa gbe ni oru 

     On yo wa pelu wa titi 

     Ife ni Olorun.


4.  Ni Sion Iao tun korin yi 

     Ife ni Olorun

     Orin t’o ga soke julo 

     Ife ni Olorun

     Titi aye aninipekun 

     Pelu awon mimo loke 

     Orin wa to dun julo ni 

     Ife ni Olorun.  Amin

English »

Update Hymn