HYMN 773

C.M.S 527 H.C 388 6s (FE 307)
“Oluwa mo fe fe bugbe ile Re”
- Ps. 26:8



1.  OLORUN, awa fe 

     Ile t’ola Re wa 

     Ayo ibugbe Re 

     Ju gbogbo ayo lo.


2.  Ile adura ni

     Fun awa omo Re 

     Jesu, O wa nibe 

     Lati gbo ebe wa.


3.  Awa fe ase Re 

    Kil’o dun to laiye 

    Nib’awon oloto 

    Nri O nitosi won.


4.  Awa fe oro Re 

     oro Alafia 

     Tinunu at’iye 

     Oro ayo titi.


5.  A fe korin anu

     T’a nri gba l’aiye yi 

     Sugbon awa fe mo

     Orin ayo t'orun.


6.  Jesu, Oluwa wa

     Busi fe wa nihin

     Mu wa de ‘nu ogo 

     Lati yin O titi.  Amin

English »

Update Hymn