HYMN 769

C.M.S 529 H.C 397 7s 6s (FE 803)
"Krist ni Ori Ijo énia Re" - Efe 5:23
Tune: Duro Duro fun Jesu



1.  JESU Oluwa ni‘se 

     lpile Ijo re

     Omi ati oro Re 

     Ni On si fi tun da

     O t’orun wa, O fi se 

     Iyawo mimo Re 

     Eje Re l'O si fi ra

     Ti O si ku fun u.


2.  N'ile gbogbo l’a sa won 

     Sugbon nwon je okan 

     Oluwa kan, gbagbo kan 

     Ati baptisi kan

     Oruko kan ni nwon nyin 

     Onje kan ni nwon nje 

     Opin kan ni nwon nlepa 

     Nipa ore-ofe.


3.  Bi aiye tile nkegan 

     Gbat’ iyonu de ba 

     Bi ‘ja on eko‐ke-ko

     Ba mu iyapa wa

     Awon mimo yio ma ke 

     Wipe ‘yo ti pe to? 

     Oru ekun fere di

     Oro orin ayo.


4.  L‘arin gbogbo 'banuje 

     At'iyonu aiye

    O nreti ojo kehin 

     Alafia lailai

     Titi y'o f’oju re ri 

     Iran ologo na

     Ti ijo nla asegun 

     Y'o d‘ijo ti nsimi.


5.  L'aiye, yi ni 'dapo

     Pelu Metalokan

     O si ni ‘dapo didun 

     Pel'awon t‘o ti sun

     A! alabukun mimo

    Oluwa, fi fun wa

     Ka ba le ri bi awon

     Ka ba O gbe ‘lorun.  Amin

English »

Update Hymn