HYMN 767

C.M.S 558 Alford D. 7.6.8. 6 (FE 80)
"A won ni aso funfun" - Ifi. 7:9



1.  EGBEGBERUN aimoye 

     Nwon wo aso ala 

     Ogun awon t'a rapada 

     Nwon kun ‘bi mole na 

     Ija won pelu ese 

     At‘iku ti pari

     E si ‘lekun wura sile 

     Fun awon asegun.


2.  Iro Halleluya won

     L'o gb'aiye orun kan 

     Iro egbegberun Harpu 

     Ndun pe ‘segun de tan 

     Ojo t'a s’eda aiye

     T’a da oril’ede

     Ayo nla pa ‘banuje re 

     Ti a fun ni kikun.


3.  A! ayo t’a ko le so 

     L’eti bebe Kenaan

     Idapo nla wo lo to yi 

     Ibi t’a ki pinya

     Oju t'o kun f’ekun ri 

     Y’o tu mo‘le ayo

     Ki yio si alaini baba 

     Opo ki yio si mo.


4.  Mu igbala nla Re wa 

     Od’agutan t’a pa

     So ‘ye awon ayanfe Re 

     Mu ‘pa Re k’o joba 

     Wa, ife oril'ede

     Da onde Re sile

     Wa fi ami' leri Re han 

     Wa, Olugbala wa.  Amin

English »

Update Hymn