HYMN 758

H.C 545 L.M (FE 792)
“On o wo inu alafia” - Isa. 57:2



1.  IGBA asale ti dun to

     Ti ara tu ohun gbogbo 

     Gbat’ itansan orun ale

     Ba ntanmole s’ohun gbogbo.


2.  Beni ‘kehin onigbagbo 

     On a simi l’alafia 

     Igbagbo t’o gbona janjan 

     A mole ninu okan re.


3.  Imole kan mo loju re

     Erin si bo ni enu re

     On f’ede t’ahon wa ko mo 

     Soro ogo t’o sunmole.


4.  Itansan ‘mole t’orun wa 

     Lati gba niyanju lona 

     Awon angeli duro yika 

     Lati gbe lo s’ibugbe won.


5.  Oluwa, jek’a lo bayi

     K’a ba O yo, k’a r’oju Re

     Te aworan Re s’okan wa 

     Si ko wa b’a ti ba O rin.  Amin

English »

Update Hymn