HYMN 757

H.C 2nd Ed 443 7s 3s (FE 791)
“Goke Jordani" - Jos 3:17



1.  A! nwon ti gun s’ebute 

     Loke orun, Loke orun

     Ebi ko ni pa won mo 

     Nown bo lowo irora 

     Loke orun, Loke orun.


2.  A! nwon ko wa fitila 

     Loke orun: loke orun 

     Mole ni I‘ojo gbogbo 

     Jesu si n’lmole won 

     Loke orun: loke orun.


3.  A! wura n’ita won je 

     Loke orun: loke orun 

     Ogo ‘be si po pupo 

     Agbo Jesu ni nwon je 

     Loke orun: loke orun.


4.  A! otutu ki mu won 

     Loke orun: loke orun

     Owore won ti koja 

     Gbogbo ojo l’o dara 

     Loke orun: loke orun.


5.  A! nwon dekun ija ja 

     Loke orun: loke orun 

     Jesu l’o ti gba won la 

     T’awon Tire l’o si nrin 

     Loke orun: loke orun.


6.  A! nwon ko ni sokun mo 

     Loke orun: loke orun 

     Jesu sa wa lodo won 

     Lodo Re ni ayo wa

     Loke orun: loke orun.


7.  A! a o dapo mo won

     Loke orun: Ioke orun

     A nreti akoko wa

    Gba Oluwa ba pe ni

    S’Oke orun, S’oke orun.  Amin

English »

Update Hymn