HYMN 754

C.M (FE788)
“Ibukun ni fun oku ti o ku nipa ti 
Oluwa" - Ifi. 14:13
Tune: Itanna t’o bo gbe



1.  ALABUKUN l’awon oku 
 
    Nipa ti Oluwa 

    Kowe re be ni Emi wi 

    Se won nto won lehin.


2.  Nwon simi ninu lala won 

     Kuro l’aginju yi

     Nwon nyo larin Egbe Mimo 

     Loke orun lohun.


3.  Ayo won ko se f’enu so 

    Larin Egbe Ogo

    Jesu ti nwon ti gbekele 

    Si ti re won lekun.


4.  Ainiye l’awon Kerubu 

    To y'ite Baba ka

    Seraf’ t’enikan ko le ka 

    Nwon nko Halleluyah!


5.  Agbagba Merinlelogun 

     Eda ‘alaye Merin 

     Nwon y’ite Olugbala ka 

     Nwon nko Mimo Mimo.


6.  Ewa ogo ‘be ti po to

     A ko le fenu so

    Didan l’awon ta se logo 

    Nwon nko orin Mose.


7.  A f’ogo fun Baba l'oke 

     A f’ogo fun Omo

     A f’ogo fun Emi Mimo 

     Metalokan lailai.  Amin

English »

Update Hymn