HYMN 753

H.C 574 7s (FE 787)
“On o wo inu Alafia” - Isa.57:2



1.  AWON t’o sowon fun wa 

     Ninu Egbe Serafu

     Nwon ti lo s’aiyeraiye 

     Ko ha ye k‘a ranti won?


2.  Awon t'o sowon fun wa 

     Larin Egbe Kerubu 

     Nwon dapo mo jo t'orun 

     lse won nto won lehin.


3.  Awon t’o sowon fun wa 

     Ninu Egbe Aladura

     Enit’ o ku ti pari 

     Ise re l’odo Jesu.


4.  Awon wonyi ti segun 

     F’Ola Olugbala won 

     Nwon ti gb’ohun Jesu pe 

     Bo s’ayo Oluwa Re.


5.  Oluwa gbadura wa 

     K’a le ni ‘po lodo Re 

     K‘a ma tan bi irawo 

     Titi lai lod’Oluwa.


6.  E f’ogo fun Baba wa, 

     E f’ogo fun Omo Re

     E f’ogo Emi Mimo

     Ogo fun metalokan.  Amin

English »

Update Hymn