HYMN 752

t.S. 43 P.M (FE 786) 
“Emi yio si pada to Olorun Io" - Oni.12:7
Tune: IpileTi Jesu fi lele



1.  ADORIN odun ni ye odun wa 

     Bi ojo alagbase

     A o ke wa lule bi itanna eweko 

     Awa a si koja lo.

Egbe: O digbose (arakunrin tabi arabinrin)

          O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin)

          O d’ojo ajinde.


2.  Koriko, b'o ku ko tun le ye mo 
 
     Iwo ku lati tun ye

     Ade ti ki sa yio je tire

     Lodo Olugbala.

Egbe: O digbose...


3.  Losu to koja, t’awa tire ni 

     Loni ipo re s'ofo

     (Arakunrin, Arabinrin)

     wa ko lo s’idale.

Egbe: O digbose...


4.  Je ki eyi je eko fun gbogbo wa,

     Lati tun wa wa se

     lgi gbigbe le wa ni iduro

     K‘a ke tutu lule.

Egbe: O digbose...


5.  Iwa wa laiye yio jeri si wa 

     Bi ‘gbehin y‘o tori

     Rere (Arakunrin, Arabinrin) 

     ti nto lehin 

     O ti se won to le se.

Egbe: O digbose...


6.  Egbe at’Ebi (Arakunrin, Arabinrin) wa

     A ba nyin daro lokan 

    Ireti mbe a o pade loke 

    Ni ojo Ajinde wa.

Egbe: O digbose (arakunrin tabi arabinrin)

          O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin)

          O d’ojo ajinde.  Amin

English »

Update Hymn