HYMN 750

S.M (FE 784) 



1.  O sun, ni Jesu wi

     Nigbati Lasaru

     Enit’o ku, ti a ti sin 

     T’a ti te s’ iboji.


2.  Oku ojo merin 

     Sun ni, loju Jesu

     On l’Ajinde ati lye 
 
     Fun awon t’o gba gbo.


3.  Ore Jesu ki ku 

     Nwon a ma parada 

     Kuro ni kokoro ile 

     S’ohun ti nfo l’oke.


4.  Sun, ara, olufe 

     Jesu duro ti o

     Ma foiya, o ti seleri 

     Ajinde f’eni Re.


5.  O fere gb’ohun na 

     Lat’oju orun re

     Ohun didun Jesu ti y’o 
 
     Pe o si ajinde.


6.  A ko ni baraje

     Bi alanireti

     O d’owuro l'a o ki o 

     Pe o si ajinde.


7.  Awa pelu y’o sun

     Li akoko tiwa

     A! k’ile mo ba gbogbo wa 

    L’ese Olugbala.  Amin

English »

Update Hymn