HYMN 747

C.M.S 138 H.C 123 10s 11s (FE 775)
“Olubukun ni oruko Oluwa Iati 
igbayi Io, ati titi Iai." - Ps.113:2



1.  RANSE Olorun, e ma kede Re

     E ma k’okiki oruko Re nla 

     E gbe oruko Jesu asegun ga 

     Ijoba Re l’ogo ohun gbogbo.


2.  Olodumare, O njoba loke

     O si sunmo wa, O mbe lodo wa, 

     Ijo nla ni y‘o korin isegun Re 

     O njewo pe, ti Jesu ni igbala.


3.  lgbala ni t’Olorun t‘o gunwa 

     Gbogb' aiye kigbe, e f’Ola f’Omo 

     Iyin Jesu nigbagbogbo Angel nke 

     N’idojubole, nwon nsin Od’agutan.


4.  E jek’awa sin, k’a f’iyin Re fun 

     Ogo, agbara, ogbon at’ipa

     Ola at’ibukun, pel‘awon Angel,

     Ope ti ko lopin at’ife titi.  Amin

English »

Update Hymn