HYMN 745

(FE 773) 
“Awon ti si ti yan tele, awon li
o si ti pe" - Rom.8:30
Tune: Oluwa Fise Ran Mi Alleluya



1.  NINU egbe Mimo yi, ti

     Moses gbe kale

     L’Oluwa s'awon Tire ni ayanfe

     Araiye le ma kegan, araiye le ma sata,

     Sugbon Serafu mo eniti nwon nsin.

Egbe: Egbe na, egbe na,

          Ta fi ran Moses

          Orimolade,

          Ta fi ife se 'pile

          K’ enikeni fese le, 

          K’ibukun aiyeraiye Ie je tiwa.


2.  O yan Baba ‘ladura lati 

      j’Oluropo re,

     Nigbati ipe de lati mu re ‘le 

     O yan awon Aposteli lati 

     gberin egbe na,

     Ki nwon mura lati tan ‘hin 

     na kale. 

Egbe: Egbe na, egbe na...


3.  Bi nwon ti je oloye ki 

     nwon je onirele,

     Lati tele ‘pase Jesu Oluwa 

     Ka le se won l'asepe bi 

     Aposteli ‘gbani,

     Ti adura won je amu‐bi-ina.

Egbe: Egbe na, egbe na...


4.  Gbogbo obinrin oloye, 

     Mary, Martha, Esther,

     Ni eto enyin oloye meteta, 

     E mura giri s'ise bi awon ti igbani,

     Nwon ko ya awon Apostili lese kan. 

Egbe: Egbe na, egbe na...


5.  Ki Ore-Ofe Jesu Kristi wa lori papo

     Ko si ba wa gbe lai ati lailai, 

     Mary, Martha, Esta, ‘ti

     Baba nla mejila.

Egbe: Egbe na, egbe na,

          Ta fi ran Moses

          Orimolade,

          Ta fi ife se 'pile

          K’ enikeni fese le, 

          K’ibukun aiyeraiye Ie je tiwa.  Amin

English »

Update Hymn