HYMN 743

t.H.C 511 8 6 6 6 (FE 769) 
“Nwon fi aho, ola ope ati iyin fun
eniti o joko lori ite" - Ifi. 4:9 
Tune: Yika ori te Olorun



1.  KERUBU ati Serafu 

     Nwon yi ‘te Baba ka 

     Nigbakugba niwaju Re

     Ni nwon nkorin ogo 

Egbe: Nkorin Ogo, Ogo, Ogo

          Nkorin Ogo, Ogo, Ogo.


2.  Gbogb' omo Egbe Kerubu 

     E toju iwa nyin

     Gbogbo Egbe t’o wa l’aiye 

     Ni ‘dapo mo t’orun.

Egbe: Nkorin Ogo...


3.  Gbogb' omo Egbe Serafu 

     E toju iwa nyin

     K’a ba le pel’awon t’orun 

     Lati ma juba Re.

Egbe: Nkorin Ogo...


4.  Awon egbe t’o wa l’orun 

     Nwon wo bi a ti nja

     Nwon si nfi ohun kan wipe 

     E ma te siwaju.

Egbe: Nkorin Ogo...


5.  Ninu iponju at’egun 

     Ninu ‘rukerudo 

     Ninu irumi at’iji 

     Yio s’ona wa fefe.

Egbe: Nkorin Ogo...


6.  Majemu ati eje Re 

     Ni igbekeke wa 

     B’ileri na tile fale 

     Sugbon ko le pe de.

Egbe: Nkorin Ogo...


7.  Nigbat’ a ba par’ise wa 

     Ni aiye osi yi

     Ade Ogo yio je tiwa 

     T’enikan ko le gba.

Egbe: Nkorin Ogo...


8.  Ogo, ola at’agbara

     Ni fun Metalokan, 

     Aiyeraiye Olorun wa 

     Amin, beni ki o ri.

Egbe: Nkorin Ogo, Ogo, Ogo

          Nkorin Ogo, Ogo, Ogo.  Amin

English »

Update Hymn