HYMN 740

C.M.S 113 O. t.H.C 235 S.M (FE 766)
“Awa ti ri irawo Re ni iha ila-orun"
 - Matt.2.2



1.  IRAWO wo l'eyi? 

     Wo b’o ti daa to 

     Amona awon keferi 

     S’odo Oba ogo.


2.  Wo awon amoye 

     Ti ila orun wa

     Nwon wa fi ori bale fun 

     Jesu Olubukun.


3.  Imole ti Emi

     Ma sai tan n'ilu wa

     Fi ona han wa, ka le to 

     Emmaueli wa.


4.  Gbogbo irun-male 

     Ati igba-male

     Ti ambo n'ile keferi 

     K’o yago fun Jesu.


5.  Ki gbogbo abore,

     Ti mbe ni Afrika

     Je amoye li otito

     Ki nwon gb’ebo Jesu.


6.  Baba Eleda wa

     Ti o fi Jesu han

     Awon Keferi igbani

     Fi han fun wa pelu.  Amin

English »

Update Hymn