HYMN 739

(FE 765)
“Se giri, ki o si mu aiye le” - Josh.1:6
Tune: Ha Egbe mi, e w’asia



1.  HA! kerubu, e se giri

     E ma jafara

     Esu ngbongun l'osan, l'oru 

     O nse lasan ni.

Egbe: Kerubu ati Serafu

           E damure nyin

           Ka le doju ‘ja ko esu 

           Ati ogun re.


2.  Ha! Serafu, e se giri 

     E ma so‘ra nu

     E ma f’aye sile f‘esu

     N’ijakadi nyin.

Egbe: Kerubu...


3.  Enyin Egbe Aladura

     Ninu Egbe yi

     K'Olorun Olodumare

     Ma je k'o re nyin.

Egbe: Kerubu...


4.  Enyin Om‘Egbe Akorin 

     E t’ohun nyin se

     A o korin Halleluyah 

     Pel' awon t'orun.

Egbe: Kerubu...


5.  Gbogbo Egbe, e ho, e yo 

     E tesiwaju

     A o segun gbogbo ota, 

     Ni oruko Re. 

Egbe: Kerubu...


6.  Ogo ni fun Baba loke 

     Ogo ni f’Omo

     Ogo ni fun Emi-Mimo 

     Lai ati lailai.

Egbe: Kerubu ati Serafu

           E damure nyin

           Ka le doju ‘ja ko esu 

           Ati ogun re.  Amin

English »

Update Hymn