HYMN 737

(FE 763)
“E lo e ma ko orile ede gbogbo”
- Matt.28:19 
Tune: Ohun Orin Awon Ilaje



1.  GBOGBO aiye Serafu de 

     Lati kede oro na 

     T’Olugbala ti fi lele 

     Lowo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba Aladura 

          Eni to d'egbe yi sile 

          Nibi Serafu, Kerubu 

          Nyin Baba Mimo logo.


2.  Adahunse, ateyepe

     Aye Egbe si sile 

     K’enyin wa ronupiwada 

     Lodo orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


3.  Babalawo, onitira

     E wa ronupiwada

     Ke wa di opo iye Re mu 

     Lodo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


4.  Sonponna ko lo sora re 

     Lodo Egbe Serafu 

     Oniwunde ti sokale 

     Sinu Egbe Kerubu.

Egbe: Lodo Baba...


5.  Egungun ati gelede 

     E wa ronupiwada 

     Ka jumo yin Olorun wa 

     Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba...


6.  lgunnu ati agemo

     E wa ronupiwada 

     K'e wa di opo iye mu 

     Lodo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


7.  A juba Olorun baba 

     Omo at‘Emi Mimo 

     Metalokan aiyeraiye 

     Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba...


8.  Kerubu ati Serafu

     T'o wa ni gbogbo aiye 

     K’awa damure wa giri 

     Lati kdede oro na.

Egbe: Lodo Baba...


9.  A ki Baba Aladura 

    T'Olorun f'Egbe yi ran

    Jerusalemu sokale 

    Lodo Orimolade. 

Egbe: Lodo Baba...


10.  Enyin ara, e ku ‘duro 

       Enyin ara, e ku ‘joko 

      Oko ‘gbala wa lode Eko 

      Lodo orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


11.  Olorun to gbo t'Elijah 

       T'o so mu lo sodo Re 

      Ko wa ran Mosisi lowo 

      Ko le wa d’odo Re.

Egbe: Lodo Baba...


12.  Olorun Abraham

       Isaac ati Jakobu 

       Baba, Omo, Emi Mimo 

       Metalokan aiyeraiye.

Egbe: Lodo Baba...


13.  Adaba orun, sokale 

       E wa ran baba lowo 

       K‘ade ogo le je tire 

       Ti enikan ko le gba.

Egbe: Lodo Baba...


14.  Michael Gabrieli, 

       Enyin agba Angeli 

       Emmanueli Oba wa 

       Metalokan la o sin.

Egbe: Lodo Baba...


15.  A f’ope f'Olorun Baba

      Omo at'Emi Mimo 

      Metalokan aiyeraiye 

      Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba Aladura 

          Eni to d'egbe yi sile 

          Nibi Serafu, Kerubu 

          Nyin Baba Mimo logo.  Amin

English »

Update Hymn