HYMN 734

t.H.C.120 D.8s 7s (FE 760)
"Iwo ma beru, nitori mo wa pelu re“
- Isa. 41:10



1.  EGBE Serafu, e dide

     E d’amure nyin giri 

     Olorun lo d’egbe yi sile 

     E ma jek‘eru ba yin

     Lo wasu ihinrere Re,

     Yio pelu wa titi d’opin, 

     Ke sa ma wo Jesu li okan 

     Titi ao fi segun.


2.  Egbe Serafu, e dide 

     Lati tan oro Olorun 

     Papa larin ilu Eko 

     F’awon to ti sako Io

     Ka le d’eni irapada 

     Larin awon ti o nsegbe lo 
 
     Lati ran won s’agbo Jesu 

     Si iye ainipekun.  Amin

English »

Update Hymn