HYMN 732

(FE 758)
“E mase gba ore-ofe Olorun lasan"
 - 2Kor. 6
Tune: Oluwa Olorun gba wa



1.  BABA Aladura mura 

     Lati pade Kerubu 

     Jesu lo pe o, lo yan o 

     Lati d’Egbe yi sile

     O si pe gbogbo aiye lati wo

     ‘ko ‘gbala yi

     B’ojo wa ti nkoja lo. 

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo - 2ce 

          Ise po t’awa o se 

          B’ojo wa ti nkoja lo.


2.  Egbe Aladura mura 

     Lati pade Kerubu

     E ma je k’amure nyin tu 

     Lati pade Kerubu

     Gbe Ida ‘segun s’oke 

     Iye s’Olorun Daniel 

     Alleluyah! Jesu mbo 

     B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo...


3.  Olorun Metalokan wa, 

     Lati gbo adura wa 

     Jesu Olugbala Oba 

     Jowo gb’ebo ope wa 

     Emi Mimo sokale

     F’ore-ofe ba wa gbe 

     Ise po t’awa o se 

     B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo...


4.  Okun fe so gbogbo wa po 

     B’ojo wa ti nkoja lo 

     Kankan lao fa won s’agbo Re 

     B’ojo wa ti nkoja lo

     Sugbon eso oro Re 

     Ndagba l’osan at’oru 

     Gb’awon to subu dide 

     B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo - 2ce 

          Ise po t’awa o se 

          B’ojo wa ti nkoja lo.  Amin

English »

Update Hymn