HYMN 731

8.7.8.7.D
Tune: Baba wa orun awa de



1.  BABA orun, 'wo lo mu wa  

     D'ojo oni l‘alafia

     Pele I’O nto isise wa

     T’O si nf'iso Re so wa 

     ‘Wo Ore at’Amona wa

     A fe fi ope fun O 

     Ao se le yin O b'o ti ye 

     Fun ‘fe Re ti ki pada?


2.  Ni gbogbo igba t’o koja 

     L’a nri anu gba lotun

     Itoju on iseun-ife

     Ko fi igba kan jin na

     Ife ati aba orun

     Mba wa gbe tosan-toru 

     Ibukun t’a ko le siro 

     Ntan imole s’ona wa.


3.  N’nu ‘danwo nla l’a ti koja 

     Iji ‘ponju ti lu wa 

     Idamu ti sokun bo wa 

     Tobe t’a ko fi ri O 

     Sibe ife Re ko ko wa 

     Sibe n’nu banuje wa 

     Iranwo t’a nse f’ara wa 

     Nipa agbara Re ni.


4.  Opo awon olufe wa

     Ti de opin ajo won 

     Ara, omo ati ore 

     Nwona lati pade wa 

     Nigbat’ ajo wa ba pari 

     Ti a si se alaisi

     Baba, mu wa la okun ja 

     Sinu mole ailopin.  Amin

English »

Update Hymn