HYMN 722

H.C 2nd Ed. 449 t.S. 65
P.M. (FE 749)
"E fi ope fun Oluwa” - Ps.105:1 
Tune: Ojo nla lojo ti mo yan



1.  OLORUN Olodumare

     A dupe fun 'dasi oni 

     Ajodun yi si tun ba wa 

     Ni ori ile agbaiye.

Egbe: A s'ope, a s'ope

              Fun idasi wa l'odun yi 

              Larin ota, larin egan 

              Larin awon oninubini 

              A s'ope, a s'ope

              Fun idasi wa l'odun yi.


2.  Ajodun oni ko ba wa

     Ha! ayo t'orun ko d'opin 

     Egbe t'o t'orun sokale 

     Iru eyi ko si laiye.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


3.  Okunrin ati Obirin 

     E mura k'e d‘amure nyin

     Omode at'agbalagba

     Ki gbogbo wa korin s’oke.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


4.  Aje, Oso, Alawirin 

     Sanponno, Ologun ika 

     Igunnu at’awon elegun 

     Ko n’ipa kan lor‘Egbe na. 

Egbe: A s'ope, a s'ope...


5.  Nigbat‘ Egbe yi ko bere 

      Awon kan nreti eleya 

     Nwon sebi egbe lasan ni 

     Nwon ko mo ise Olorun.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


6.  Metalokan l’Olorun wa

     Olorun ti ko n’ipekun

     Baba, Omo, Emi Mimo 

     Gbogbo won lo nsise won po.

Egbe: A s'ope, a s'ope

              Fun idasi wa l'odun yi 

              Larin ota, larin egan 

              Larin awon oninubini 

              A s'ope, a s'ope

              Fun idasi wa l'odun yi.  Amin

English »

Update Hymn