HYMN 721

(FE 748)
"Alaye alaye on ni yima yin O” - Isa.38:19 
Tune: Ibase p’Oluwa (K & S 82)



1.  OJO nla l‘eyi je

     T’a nse Ajodun wa 
 
     Kerubu.., e ho ye 

     Serafu, e gberin. 

Egbe: Halleluyah, Halleluyah 

           S’Oba wa

           Eniti o da wa si

           LAti tun ri odun yi 

           Ogo f’oruko Re.


2.  Orun pe l’Osupa

     E fi ayo nyin han

     F’emi wa to d’oni

     Larin Egbe Kerubu.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


3.  Sure fun wa loni

     Baba Mimo t‘orun

     Ma je ki a rahun 

     Nikehin aiye wa.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


4.  lru Egbe Seraf‘ 

     Larin Ilu Afrika

     Igba wa sunmole

     T'ao bo l’oko eru.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


5.  A dupe, Oluwa

     Fun Ajodun oni

     T’o s'oju emi wa

    Lori ‘le alaye.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


6.  Ajodun nla kan mbe

     T'a o se loke Orun 

     Pelu awon Mimo

     Fun iyin Oluwa.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


7.  A dupe, Oluwa

     Pe O ti gbo tiwa

     Ma jek‘a d’ese mo

     K‘a l‘ayo nikehin.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah 

           S’Oba wa

           Eniti o da wa si

           LAti tun ri odun yi 

           Ogo f’oruko Re.  Amin

English »

Update Hymn