HYMN 720

7s 6s (FE 747)
"Awa ri ohun abami Ioni" - Luku. 5:26
Tune: Gbekele Onigbagbo



1.  OJO ayo l‘eyi je 

     Awa ns'ajodun wa 

     Kerubu npe Serafu

     E jade wa woran.

Egbe: Halleluyah! korin kikan soke

          Halleluyah! f'Oba Olorun wa.


2.  Egbe ogun orun nki wa 

     Pe mase jafara

     Akoko die lo ku 

    T’aiye y’o koja Io.

Egbe: Halleluyah!...


3.  Ohun iyanu l’eyi 

     Nipa ti Egbe na 

     Nigbat’ igbagbo ti se 

     A ko ri iru eyi ri.

Egbe: Halleluyah!...


4.  Gbogb’ awon alailera 

     T’o wa nin’Egbe na 

     Okunrin at‘Obinrin 

     Njeri si eyi na.

Egbe: Halleluyah!...


5.  Won to wa nigberiko 

     Njeri si otito

     Pe aje ko n‘ipa mo 

     'Nu egbe Serafu.

Egbe: Halleluyah!...


6.  Awon t’o wa n‘idale 

     Nwon nsope, nwon si njo 

     Soponna ko n'ipa mo

     ‘Nu egbe kerubu.

Egbe: Halleluyah!...


7.  Serafu ma gbode kan 

     Ko si ‘ru eyi ri

     Kerubu ma gbode kan 

     Nwon nji oku dide.

Egbe: Halleluyah!...


8.  Ogo ni fun Baba l’oke 

     Ogo ni fun Omo

     Ogo ni fun Emi Mimo 

     Metalokan lailai.

Egbe: Halleluyah! korin kikan soke

          Halleluyah! f'Oba Olorun wa.  Amin

English »

Update Hymn