HYMN 72

(FE 89)
"Oluwa mo awon ti se Tire" - II Tim. 1:19



1.  OBA awon eni Mimo

     T'o mo ye awon ‘rawo

     Opo enit' Eda gbagbe

     Wa yika ite Re lati,

Egbe:  Mimo Mimo, Mimo Mimo, Mimo Mimo

           Lo ye O.

           Iwo I'a ba ma f' iyin fun

           Olorun, Edumare.


2.  Enit' o wa ninu ‘mole

     T oju enikan ko ri

     Mose ri akehinsi Re

     Oju Mose ran b'orun.

Egbe:  Mimo Mimo...


3.  Mole ti ‘kuku aiye bo

     Ntan mole roro loke

     Nwon je omo alade l'orun

     Eda gbagbe won t‘aiye.

Egbe:  Mimo Mimo...


4.  Lala at'iya won fun O,

     Eda ko rohin re mo

     Iwa rere won farasin

     Oluwa nikan lo mo

Egbe:  Mimo Mimo...


5.  Nwon farasin fun wa sugbon

     A ko-won s'iwe iye

     lgbagbo, adura, suru

     Lala on’jakadi won

Egbe:  Mimo Mimo...


6.  Nwon mo isura Re lohun

     Ka wa mo won Oluwa

     Nigba’O ba nsiro oso

     Ti mbe lara ade Re.

Egbe:  Mimo Mimo...


7.  E wole f’Oba Ologo

     Serafu e wole fun

     Niwaju ite Jehovah

     Olorun Metalokan.

Egbe:  Mimo Mimo...


8.  E wole f’Oba Ologo

     Kerubu e wole fun

     Niwaju ite Jehovah

     Olorun Metalokan.

Egbe:  Mimo Mimo...  Amin

English »

Update Hymn