HYMN 718

8.7.8.7.4.7
Tune: Ma toju mi Jihovah Nla



1.  OLORUN Oluwa l'oba 

     Aye mbe niwaju Re

     Nibi t’awon angel nsin I 

     L’O gunwa ni ite Re 

     Eni Mimo

     Obangiji, On l'Oba.


2.  Oba Ogo Ii Olorun 

     Sion royin Re k‘aye 

     lsra-eli ti igbani 

     Kede itan oto Re 

     Eni Mimo

     Mimo li oruko Re.


3.  Li atijo, ni ‘gba ewu 

     T’awon ojise Re be

     O gbo gbe awon eniyan Re 

     N'nu eru won, O dahun 

     Eni Mimo

     Won ri n'tosi gba won p'e.


4.  Awon l‘afun l’ofin mimo 

     Lat' inu awosanma

     Ilana mimo ti won ru 

     Mu ki O binu si won

     Eni Mimo

     Won kanu fun ese won.


5.  Sugbon Baba won fiji won 

     Gba won tun safari Re

     O mura tan lati gba won

     O f‘ife gba won pada

     Eni Mimo

     Awa na nw’or'ofe Re.


6.  Baba wa n’iyonu n'nu Kristi 

     Y‘o mu ileri Re se

     Wa, k‘a gbe ga, gbogbo'alaye 

     E wa soke mimo Re!

     Eni Mimo 

     E sin loke mimo Re.  Amin

English »

Update Hymn