HYMN 716

1.  GBO ohun Jesu ti nke pe 

     Tani y‘o sise loni

     Oko pon pupo fun ‘kore 

     Tani y’o lo ko wa l’e 

     Kikan kikan l’Oluwa npe 

     Ebun nla ni y’O fun o

     Tani y’o fl ayo dahun 

     Pe” Emi ni yi ran mi?


2.  B’iwo ko le okun lo 

     Lati w’awon keferi

     O le ri won nitosi re 

     Nwon wa l’enu ona 

     B’o ko le fi wura tore 

     Ebun miran ko kere 

     Die t’o sise fun Jesu 

     ‘Yebiye ni l'oju Re.


3.  B’iwo ko le se alore 

     L‘ori odi Sioni

     Lati t’oka s’ona orun 

     Lati f’iye lo eda

     Wole f'adura at’ore 

     Se ohun t’Olorun wi 

     Wo le se gegebi Aaron

     T’o gbowo woli soke.


4.  Ma je k’a gbo ki o wipe 

     Ko si nkan t’emi le se 

     Nigbat’ emi eniyan nku 

     Ti Oluwa si npe o

     F’ayo gba ise t’O ran o, 

     Fise Re se ayo re

     Gbat’ o npe o, tara dahun 

     Pe emi ni yi, ran mi.  Amin

English »

Update Hymn